Mark 12:28-31

Òfin tí ó ga jùlọ

28 aỌ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”

29 bJesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. 30Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’ 31 cÈkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”

Copyright information for YorBMYO